1 Samuel 21:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn iranṣẹ Akiṣi sì sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ Dafidi, ọba ilẹ̀ rẹ̀ kọ́ nìyí, tí àwọn obinrin ń kọrin nípa rẹ̀ pé: ‘Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi sì pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iranṣẹ Akiṣi si wi fun u pe, Ṣe eyiyi ni Dafidi ọba ilẹ na? nwọn kò ha ti da ti nwọn si gberin nitori rẹ̀ ni ijo, pe, Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbãrun tirẹ̀?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìránṣẹ́ Ákíṣì sì wí fún un pé, “Èyí há kọ́ ní Dáfídì ọba ilẹ̀ náà? Ǹjẹ́ wọn kò ha ti dárin ti wọ́n sì gbe orin nítorí rẹ̀, tí wọ́n sì jó pé, “ ‘Ṣọ́ọ̀lù pá ẹgbẹ̀rún tírẹ. Dáfídì sì pa ẹgbàarún tirẹ̀’?”