1 Samuel 21:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Akiṣi bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ kò rí i pé aṣiwèrè ni ọkunrin yìí ni, kí ló dé tí ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Akiṣi wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ẹnyin ri pe ọkunrin na nhuwà aṣiwere; njẹ nitori kini ẹnyin ṣe mu u tọ̀ mi wá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ákíṣì wí fún àwọn ìrańṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wó o, nítorí kín ni ẹ̀yin ṣe mú un tọ̀ mí wá.