1 Samuel 21:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó dáhùn pé, “Ọba ni ó rán mi ní iṣẹ́ pataki kan, ó sì ti sọ fún mi pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ nípa iṣẹ́ tí òun rán mi. Mo sì ti sọ fún àwọn iranṣẹ mi pé kí wọ́n pàdé mi ní ibìkan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun Ahimeleki alufa pe, ọba paṣẹ iṣẹ kan fun mi, o si wi fun mi pe, Máṣe jẹ ki ẹnikan mọ̀ idi iṣẹ na ti mo rán ọ, ati eyi ti emi ti paṣẹ fun ọ; emi si yàn awọn iranṣẹ mi si ibi bayi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún Áhímélékì àlùfáà pé, “Ọbá pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí.