1 Samuel 21:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Alufaa náà sì dáhùn pé, “N kò ní burẹdi lásán, àfi èyí tí ó jẹ́ mímọ́. Mo lè fún ọ tí ó bá dá ọ lójú pé àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ ti pa ara wọn mọ́, tí wọn kò sì bá obinrin lòpọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alufa na si da Dafidi lohùn o si wipe, Kò si akara miran li ọwọ́ mi bikoṣe akara mimọ́; bi awọn ọmọkunrin ba ti pa ara wọn mọ kuro lọdọ obinrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà náà sí dá Dáfídì lóhùn ó sì wí pé, “Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́; Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pá ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin!”