1 Samuel 21:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi dáhùn pé, “Àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu mi a máa pa ara wọn mọ́ nígbà tí a bá ń lọ fún iṣẹ́ tí kò ṣe pataki, kí á tó wá sọ ti iṣẹ́ yìí, tí ó jẹ́ iṣẹ́ pataki?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si da alufa na lohùn, o si wi fun u pe, Nitotọ a ti pa ara wa mọ kuro lọdọ obinrin lati iwọn ijọ mẹta wá, ti emi ti jade; gbogbo nkan awọn ọmọkunrin na li o mọ́, ati akara na si wa dabi akara miran, ye e pãpã nigbati o jẹ pe omiran wà ti a yà si mimọ́ loni ninu ohun elo na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin nígbàkùúgbà ti mo bá jáde ìrìn-àjò, gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, pàápàá nígbà ìrìn-àjò kékèké; kò há ní mọ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ lónìí bí?”