1 Samuel 21:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Doegi, olórí darandaran Saulu, ará Edomu wà níbẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ó ń jọ́sìn níwájú OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin kan ninu awọn iranṣẹ Saulu si mbẹ nibẹ li ọjọ na, ti a ti da duro niwaju Oluwa; orukọ rẹ̀ si njẹ Doegi, ara Edomu olori ninu awọn darandaran Saulu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin kan nínú àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ níbẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí a tí dá dúró síwájú OLÚWA; orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Dóégì, ará Édómù olórí nínú àwọn darandaran Ṣọ́ọ̀lù.