1 Samuel 22:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ǹjẹ́ èyí ha ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Rárá o! Nítorí náà kí ọba má ṣe ka ẹ̀sùn kankan sí èmi ati ìdílé baba mi lẹ́sẹ̀, nítorí pé, èmi iranṣẹ rẹ, kò mọ nǹkankan nípa ọ̀tẹ̀ tí Dafidi dì sí ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oni li emi o ṣẹṣẹ ma bere li ọwọ́ Ọlọrun fun u bi? ki eyini jinà si mi: ki ọba ki o máṣe ka nkankan si iranṣẹ rẹ̀ lọrùn, tabi si gbogbo idile baba mi: nitoripe iranṣẹ rẹ kò mọ̀ kan ninu gbogbo nkan yi, diẹ tabi pupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òní l'èmi ó ṣẹṣẹ̀ máa béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un bí? Kí èyí jìnnà sí mi: kí ọba má ṣe ka nǹkan kan sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́rùn, tàbí sí gbogbo ìdílé baba mi: nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ̀ kò mọ̀kan nínú gbogbo nǹkan yìí, díẹ̀ tabi púpọ̀.”