1 Samuel 22:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọba bá pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ pa àwọn alufaa OLUWA nítorí pé wọ́n wà lẹ́yìn Dafidi, wọ́n mọ̀ pé ó ń sá lọ, wọn kò sì sọ fún mi.” Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun náà kọ̀ láti pa àwọn alufaa OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọba si wi fun awọn aṣaju ti ima sare niwaju ọba, ti o duro tì i, pe, Yipada ki ẹ si pa awọn alufa Oluwa; nitoripe ọwọ́ wọn wà pẹlu Dafidi, ati nitoripe, nwọn mọ̀ igbati on sa, nwọn kò si sọ ọ li eti mi. Ṣugbọn awọn iranṣẹ ọba ko si jẹ fi ọwọ́ wọn le awọn alufa Oluwa lati pa wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba sì wí fún àwọn aṣáájú ti máa ń sáré níwájú ọba, tí ó dúró tì í pé, “Yípadà kí ẹ sì pa àwọn àlùfáà OLÚWA; nítorí pé ọwọ́ wọn wà pẹ̀lú Dáfídì, àti nítorí pé wọ́n mọ ìgbà tí òun sá, wọn kò sì sọ ọ́ létí mi,” Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ ọba kò sì jẹ́ fi ọwọ́ wọn lé àwọn àlùfáà OLÚWA láti pa wọ́n.