1 Samuel 22:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Nobu, ìlú àwọn alufaa, atọkunrin atobinrin, àtọmọdé, àtọmọ ọwọ́, ati mààlúù, ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati aguntan, wọ́n sì pa gbogbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si fi oju ida pa ara Nobu, ilu awọn alufa na ati ọkunrin ati obinrin, ọmọ wẹrẹ, ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agutan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì fi ojú idà pa ara Nóbù, ìlú àwọn àlùfáà náà àti ọkùnrin àti obìnrin, ọmọ wẹ́wẹ́, àti àwọn tí ó wà lẹ́nu ọmú, àti màlúù, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti àgùntàn.