1 Samuel 22:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Saulu jókòó ní abẹ́ igi tamarisiki ní orí òkè kan ni Gibea, ọ̀kọ̀ rẹ̀ wà ní ọwọ́ rẹ̀, àwọn olórí ogun rẹ̀ sì dúró yí i ká, ó gbọ́ pé wọ́n rí Dafidi ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si gbọ́ pe a ri Dafidi ati awọn ọkunrin ti o wà lọdọ rẹ̀; Saulu si ngbe ni Gibea labẹ igi kan ni Rama; ọkọ̀ rẹ̀ si mbẹ lọwọ rẹ̀, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ si duro tì i;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù si gbọ́ pé a rí Dáfídì àti àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; Ṣọ́ọ̀lù sì ń bẹ ní Gíbéà lábẹ́ igi kan ní Rámà; ọ̀kọ̀ rẹ̀ sì ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì dúró tì í.