1 Samuel 22:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣé nítorí náà ni ẹ ṣe gbìmọ̀ burúkú sí mi, tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò fi sọ fún mi pé ọmọ mi bá ọmọ Jese dá majẹmu. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì káàánú mi láàrin yín, kí ó sì sọ fún mi pé, ọmọ mi ń ran iranṣẹ mi lọ́wọ́ láti ba dè mí, bí ọ̀rọ̀ ti rí lónìí yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti gbogbo nyin fi dimọlù si mi, ti kò fi si ẹnikan ti o sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi ti ba ọmọ Jesse mulẹ, bẹ̃ni kò si si ẹnikan ninu nyin ti o ṣanu mi, ti o si sọ ọ li eti mi pe, ọmọ mi mu ki iranṣẹ mi dide si mi lati ba dè mi, bi o ti ri loni?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí gbogbo yín di ìmọ̀lù sí mi, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó sọ létí mi pé, ọmọ mi ti bá ọmọ Jésè mulẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kó sì sí ẹnìkan nínú yín tí ó ṣàánú mi, tí ó sì sọ ọ́ létí mi pé, ọmọ mi mú kí ìránṣẹ́ mi dìde sí mi láti ba dè mí, bí ó ti rí lónìí.”