1 Samuel 23:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, Dafidi ati ẹgbẹta (600) àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ kúrò ní Keila lẹsẹkẹsẹ. Nígbà tí Saulu gbọ́ pé Dafidi ti kúrò ní Keila, kò lọ gbógun ti Keila mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn to ẹgbẹta enia si dide, nwọn lọ kuro ni Keila, nwọn si lọ si ibikibi ti nwọn le lọ. A si wi fun Saulu pe, Dafidi ti sa kuro ni Keila; ko si lọ si Keila mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n tó ẹgbẹ̀ta ènìyàn sì dìdé, wọ́n lọ kúrò ní Kéílà, wọ́n sì lọ sí ibikíbi tí wọ́n lè rìn lọ. A sì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Dáfídì ti sá kúrò ní Kéílà; kò sì lọ sí Kéílà mọ́.”