1 Samuel 23:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá pada sí Sifi ṣáájú Saulu. Ṣugbọn Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ ti wà ní aṣálẹ̀ Maoni tí ó wà ní Araba lápá ìhà gúsù Jeṣimoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si dide, nwọn si ṣaju Saulu lọ si Sifi: ṣugbọn Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ wà li aginju Maoni, ni pẹtẹlẹ niha gusu ti Jeṣimoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì dìde, wọ́n sì ṣáájú Ṣọ́ọ̀lù lọ sí Sífì: ṣùgbọ́n Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wà ní ihà Máónì, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ níhà gúsù ti Jésímónì.