1 Samuel 23:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ láti wá Dafidi. Ṣugbọn Dafidi gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì lọ sá pamọ́ sí ibi òkúta kan tí ó wà ní aṣálẹ̀ Maoni. Nígbà tí Saulu gbọ́, ó lépa Dafidi lọ sí aṣálẹ̀ Maoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ iwá a. Nwọn si sọ fun Dafidi: o si sọkalẹ wá si ibi okuta kan, o si joko li aginju ti Maoni. Saulu si gbọ́, o si lepa Dafidi li aginju Maoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ ń wá a. Wọ́n sì sọ fún Dáfídì: ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí ibi òkúta kan, ó sì jókòó ní ihà ti Máónì. Ṣọ́ọ̀lù sì gbọ́, ó sì lépa Dáfídì ní ihà Máónì.