1 Samuel 23:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ wà ní apá kan òkè náà, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì wà ní apá keji. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ń múra láti sá fún Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ nítorí pé wọ́n ń rọ̀gbà yí wọn ká láti mú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si nrin li apakan oke kan, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ li apa keji oke na: Dafidi si yara lati sa kuro niwaju Saulu; nitoripe Saulu ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti rọ̀gba yi Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ka lati mu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì ń rin apákan òkè kan, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní apákejì òkè náà. Dáfídì sì yára láti sá kúrò níwájú Ṣọ́ọ̀lù; nítorí pé Ṣọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ti rọ̀gbà yí Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ká láti mú wọn.