1 Samuel 23:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi tún bèèrè lọ́wọ́ OLUWA lẹ́ẹ̀kan sí i pé, bóyá kí òun lọ tabi kí òun má lọ. OLUWA sì dáhùn pé, “Lọ sí Keila nítorí n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ará Filistia.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si tun bere lọdọ Oluwa. Oluwa si da a lohùn, o si wipe, Dide, ki o sọkalẹ lọ si Keila, nitoripe emi o fi awọn ara Filistia na le ọ lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì tún béèrè lọ́dọ OLÚWA. OLÚWA sì dá a lóhùn, ó sì wí pé, “Dìde, kí o sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, nítorí pé èmi ó fi àwọn ará Fílístínì náà lé ọ lọ́wọ́.”