1 Samuel 23:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá lọ gbógun ti àwọn ará Filistia ní Keila, wọ́n pa ọpọlọpọ ninu wọn, wọ́n sì kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe gba àwọn ará Keila sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ si Keila, nwọn si ba awọn ara Filistia jà, nwọn si ko ohun ọsìn wọn, nwọn si fi iparun nla pa wọn. Dafidi si gbà awọn ara Keila silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì lọ sí Kéílà, wọ́n sì bá àwọn ará Fílístínì jà, wọ́n sì kó ohun ọ̀sìn wọn, wọ́n sì fi ìparun ńlá pa wọ́n. Dáfídì sì gba àwọn ará Kéílà sílẹ̀.