1 Samuel 23:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu bá pe gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ láti gbógun ti Keila kí wọ́n sì ká Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ mọ́ ìlú náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si pe gbogbo awọn enia na jọ si ogun, lati sọkalẹ lọ si Keila, lati ká Dafidi mọ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, láti ká Dáfídì mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.