1 Samuel 24:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nisinsinyii, o rí i dájú pé OLUWA fi ọ́ lé mi lọ́wọ́ ninu ihò àpáta. Àwọn kan ninu àwọn ọkunrin mi rọ̀ mí pé kí n pa ọ́, ṣugbọn mo kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Mo sọ fún wọn pé, n kò ní fọwọ́ mi kàn ọ́, nítorí pé ẹni àmì òróró OLUWA ni ọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wõ, oju rẹ ri loni, bi Oluwa ti fi iwọ le mi li ọwọ́ loni ni iho nì: awọn kan ni ki emi ki o pa ọ: ṣugbọn emi dá ọ si; emi si wipe, emi ki yio nawọ́ mi si oluwa mi, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa li on iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wò ó, ojú rẹ́ ríi lónìí, bí OLÚWA ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò; àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ; ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí; ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni-àmì-òróró OLÚWA ni òun jẹ́.’