1 Samuel 24:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wò ó! Baba mi, wo etí aṣọ rẹ tí mo mú lọ́wọ́ yìí, ǹ bá pa ọ́ bí mo bá fẹ́, ṣugbọn kàkà bẹ́ẹ̀, mo gé etí aṣọ rẹ. Ó yẹ kí èyí fihàn ọ́ pé n kò ní ìfẹ́ láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ, tabi láti pa ọ́. Ṣugbọn ìwọ ń lé mi kiri láti pa mí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ṣe ọ́ níbi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu, baba mi, wõ, ani wo eti aṣọ rẹ li ọwọ́ mi; nitori emi ke eti aṣọ rẹ, emi ko si pa ọ, si wò, ki o si mọ̀ pe, kò si ibi tabi ẹ̀ṣẹ li ọwọ́ mi, emi kò si ṣẹ̀ ọ, ṣugbọn iwọ ndọdẹ ẹmi mi lati gba a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mi mi láti gbà á.