1 Samuel 24:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Saulu dé ibi tí àwọn agbo aguntan kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó rí ihò àpáta ńlá kan lẹ́bàá ibẹ̀, ó sì wọ inú rẹ̀ lọ láti sinmi. Ihò náà jẹ́ ibi tí Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ farapamọ́ sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si de ibi awọn agbo agutan ti o wà li ọ̀na, ihò kan si wà nibẹ, Saulu si wọ inu rẹ̀ lọ lati bo ẹsẹ rẹ̀: Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si mbẹ lẹba iho na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Ṣọ́ọ̀lù sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹṣẹ̀ rẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà.