1 Samuel 24:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Dafidi sọ fún un pé, “Òní gan-an ni ọjọ́ tí OLUWA ti sọ fún ọ nípa rẹ̀, pé òun yóo fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, kí o lè ṣe é bí ó ti wù ọ́.” Dafidi bá yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí Saulu wà, ó sì gé etí aṣọ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọkunrin Dafidi si wi fun u pe, Wõ, eyi li ọjọ na ti Oluwa wi fun ọ pe, Wõ, emi o fi ọta rẹ le ọ li ọwọ́, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi o ti tọ li oju rẹ. Dafidi si dide, o si yọ lọ ike eti aṣọ Saulu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọkùnrin Dáfídì sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí OLÚWA wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dáfídì sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Ṣọ́ọ̀lù.