1 Samuel 25:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi sì pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sán idà yín mọ́ ìdí.” Gbogbo wọn sì ṣe bí ó ti wí; òun pàápàá sì sán idà tirẹ̀ náà mọ́ ìdí. Irinwo ninu àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ bá a lọ; igba (200) sì dúró ti ẹrù wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Ki olukuluku nyin ki o di idà rẹ̀ mọ idi. Olukuluku ọkunrin si di idà rẹ̀ mọ idi; ati Dafidi pẹlu si di idà tirẹ̀: iwọn irinwo ọmọkunrin si goke tọ Dafidi lẹhin; igba si joko nibi ẹrù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sí wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Kí olúkúlùkù yín ó di idá rẹ́ mọ́ idi,” Olúkúlùkù ọkùnrin sì di idà tirẹ́ rẹ́ mọ̀ ìdí; àti Dáfídì pẹ̀lú sì di idà tirẹ̀; ìwọ̀n irinwó ọmọkùnrin si gòkè tọ Dáfídì lẹ́yin; igba si jókòó nibi ẹrù.