1 Samuel 25:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jọ̀wọ́ ro ọ̀rọ̀ náà dáradára, kí o sì pinnu ohun tí o bá fẹ́ ṣe; nítorí pé wọ́n ti gbèrò ibi sí oluwa wa ati ìdílé rẹ̀, ọlọ́kàn líle sì ni oluwa wa, ẹnikẹ́ni kò lè bá a sọ̀rọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ si ro o wò, ki o si mọ̀ eyiti iwọ o ṣe; nitoripe ati gbero ibi si oluwa wa, ati si gbogbo ile rẹ̀: on si jasi ọmọ Beliali ti a ko le sọ̀rọ fun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́, rò ó wò, kí ìwọ sì mọ èyí ti ìwọ yóò ṣe; nítorí pé a ti gbèrò ibi sí olúwa wa, àti sí gbogbo ilé rẹ̀; òun sì jásí ọmọ Bélíálì tí a kò le sọ̀rọ̀ fún.”