1 Samuel 25:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA tìkararẹ̀ ni ó ti ká ọ lọ́wọ́ kò láti má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ati láti má gbẹ̀san. Nisinsinyii, oluwa mi, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ati àwọn tí wọn ń ro ibi sí ọ yóo dàbí Nabali.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ, oluwa mi, bi Oluwa ti wà lãye, ati bi ẹmi rẹ si ti wà làye, bi Oluwa si ti da ọ duro lati wá ta ẹjẹ silẹ, ati lati fi ọwọ́ ara rẹ gbẹsan; njẹ, ki awọn ọta rẹ, ati awọn ẹniti ngbero ibi si oluwa mi ri bi Nabali.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́ OLÚWA mi, bi OLÚWA ti wà láàyè, àti bí ẹ̀mí rẹ̀ si ti wà láàyè, bi OLÚWA sì ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ silẹ̀, àti láti fi ọwọ́ ara rẹ gbẹ̀san; ǹjẹ́, kí àwọn ọ̀ta rẹ, àti àwọn ẹni tí ń gbérò ibi sí olúwa mi rí bi Nábálì.