1 Samuel 25:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jọ̀wọ́ dáríjì mí fún gbogbo àìṣedéédé mi. Dájúdájú OLUWA yóo jẹ́ kí o jọba ati àwọn ọmọ rẹ pẹlu. Nítorí pé ogun OLUWA ni ò ń jà, o kò sì hùwà ibi kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi bẹ̀ ọ, fi irekọja iranṣẹbinrin rẹ ji i: nitori ti Oluwa yio sa ṣe ile ododo fun oluwa mi, nitori ogun Oluwa ni oluwa mi njà; a kò si ri ibi lọwọ rẹ ni gbogbo ọjọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá arábìnrin rẹ jìn ní: nítorí OLÚWA yóò fi ìdí ìjọba olúwa mi múlẹ̀, nítorí pé ó ja ogun OLÚWA. Nítorí náà kí a má ri ibi kan ni ọwọ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí ó wà láàyè.