1 Samuel 25:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ẹnikẹ́ni bá sì ń gbèrò láti ṣe ọ́ ní ibi tabi láti pa ọ́, OLUWA yóo dáàbò bò ọ́ bí eniyan ti ń dáàbò bo ohun ìní olówó iyebíye. Ṣugbọn àwọn ọ̀tá rẹ ni a óo parun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin kan si dide lati ma lepa rẹ, ati lati ma wá ẹmi rẹ: ṣugbọn a o si di ẹmi oluwa mi ninu idi ìye lọdọ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹmi awọn ọta rẹ li a o si gbọ̀n sọnù gẹgẹ bi kànakana jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi mú láàyè lọdọ OLÚWA Ọlọ́run rẹ; àti ẹ̀mí àwọn ọ̀ta rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde.