1 Samuel 25:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
o kò ní ní ìbànújẹ́ ọkàn pé o ti paniyan rí láìnídìí tabi pé o ti gbẹ̀san ara rẹ. Nígbà tí OLUWA bá sì bukun ọ, jọ̀wọ́ má ṣe gbàgbé èmi iranṣẹbinrin rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyi ki yio si jasi ibinujẹ fun ọ, tabi ibinujẹ ọkàn fun oluwa mi, nitoripe iwọ ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ, tabi pe oluwa mi gbẹsan fun ara rẹ̀: ṣugbọn nigbati Oluwa ba ṣe ore fun oluwa mi, njẹ ranti iranṣẹbinrin rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èyí kì yóò sì jásí ìbànújẹ fún ọ, tàbí ìbànújẹ́ ọkàn fún olúwa mi, nítorí pé ìwọ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, tàbí pé olúwa mi gbẹ̀san fún ara rẹ̀: ṣùgbọ́n nígbà tí OLÚWA ba ṣe oore fún olúwa mi, ǹjẹ́ rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ!”