1 Samuel 25:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ti dá mi dúró láti má ṣe ọ́ ní ibi. Ṣugbọn mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí mi, bí o kò bá yára láti pàdé mi ni, gbogbo àwọn ọkunrin ilé Nabali ni ìbá kú kí ilẹ̀ ọ̀la tó mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ bi Oluwa Ọlọrun Israeli ti mbẹ, ti o da mi duro lati pa ọ lara, bikoṣepe bi iwọ ti yara ti o si ti wá pade mi, nitotọ ki ba ti kù fun Nabali di imọlẹ owurọ ninu awọn ti o ntọ̀ sara ogiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítòòtọ́ ni OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì tí ń bẹ, tí ó da mi dúró láti pa ọ́ lára bí kò ṣe pé bí ìwọ ti yára tí ó sì wá pàdé mi, nítòótọ́ kì bá tí kù fún Nábálì di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀.”