1 Samuel 25:36 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Abigaili pada dé ilé ó bá Nabali ninu àsè bí ọba. Inú rẹ̀ dùn nítorí pé ó ti mu ọtí ní àmupara. Abigaili kò sì sọ nǹkankan fún un títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abigaili si tọ̀ Nabali wá, si wõ, on si se asè ni ile rẹ̀ gẹgẹ bi ase ọba; inu Nabali si dùn nitoripe, o ti mu ọti li amupara; on kò si sọ nkan fun u, diẹ tabi pupọ: titi di imọlẹ owurọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábígáílì sì tọ Nábálì wá, sì wò ó, òun sì ṣe àṣè ni ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àsè ọba: inú Nábálì sì dùn nítorí pé, ó ti mú ọtí ni àmupara; òun kò si sọ nǹkan fún un, díẹ̀ tàbí púpọ̀: títí di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀