1 Samuel 25:39 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Nabali ti kú, ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA tí ó gbẹ̀san lára Nabali nítorí àfojúdi tí ó ṣe sí mi. Ìyìn ni fún OLUWA tí ó sì fa èmi iranṣẹ rẹ̀ sẹ́yìn kúrò ninu ṣíṣe ibi. OLUWA ti jẹ Nabali níyà fún ìwà burúkú rẹ̀.” Dafidi bá ranṣẹ sí Abigaili pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si gbọ́ pe Nabali kú, o si wi pe, Iyin ni fun Oluwa ti o gbeja gigàn mi lati ọwọ́ Nabali wá, ti o si da iranṣẹ rẹ̀ duro lati ṣe ibi: Oluwa si yi ikà Nabali si ori on tikalarẹ̀. Dafidi si ranṣẹ, o si ba Abigaili sọ̀rọ lati mu u fi ṣe aya fun ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì gbọ́ pé Nábálì kú, ó sì wí pé, “Ìyìn ni fún OLÚWA tí o gbéjà gígàn mi láti ọwọ́ Nábálì wá, tí ó sì dá ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró láti ṣe ibi: OLÚWA sì yí ikà Nábálì sí orí òun tìkárarẹ̀.” Dáfídì sì ránṣẹ́, ó sì ba Ábígáílì sọ̀rọ̀ láti mú un fi ṣe aya fún ara rẹ̀.