1 Samuel 25:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ó bá rán ọdọmọkunrin mẹ́wàá lọ sí Kamẹli láti lọ rí Nabali, kí wọ́n sì kí i ní orúkọ òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si ran ọmọkunrin mẹwa, Dafidi si sọ fun awọn ọdọmọkunrin na pe, Ẹ goke lọ si Karmeli, ki ẹ si tọ Nabali lọ, ki ẹ si ki i li orukọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì rán ọmọkùnrin mẹwàá, Dáfídì sì sọ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà pé, “Ẹ gòkè lọ sí Kámẹ́lì, kí ẹ sì tọ Nábálì lọ, kí ẹ sì kí i ni orúkọ mi.