1 Samuel 25:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo gbọ́ pé ò ń gé irun àwọn aguntan rẹ, mo sì fẹ́ kí o mọ̀ pé àwọn olùṣọ́ aguntan rẹ wà lọ́dọ̀ wa fún ìgbà pípẹ́, n kò sì ṣe wọ́n ní ibi kankan. Kò sí ohun tí ó jẹ́ tiwọn tí ó sọnù ní gbogbo ìgbà tí wọ́n wà ní Kamẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ mo gbọ́ pe, awọn olùrẹrun mbẹ lọdọ rẹ; Wõ, awọn oluṣọ agutan rẹ ti wà lọdọ wa, awa kò ṣe wọn ni iwọsi kan, bẹ̃ni ohun kan ko si nù lọwọ wọn, ni gbogbo ọjọ ti nwọn wà ni Karmeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ǹjẹ́ mo gbọ́ pé, àwọn olùrẹ̀run ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ Wò ó, àwọn olùsọ́ àgùntàn rẹ ti wà lọ́dọ̀ wa àwa kò sì pà wọ́n lára, wọn kò sì sọ ohunkóhun nù ní gbogbo ọjọ́ tí wọ́n wà ní Kámẹ́lì.