1 Samuel 25:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọdọmọkunrin rẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ. Ọjọ́ ọdún ni ọjọ́ òní, nítorí náà jẹ́ kí àwọn ọmọkunrin yìí rí ojurere lọ́dọ̀ rẹ. Jọ̀wọ́ mú ohunkohun tí ó bá wà ní àrọ́wọ́tó rẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ, ati fún èmi Dafidi, ọmọ rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi awọn ọmọkunrin rẹ lere, nwọn o si sọ fun ọ. Nitorina jẹ ki awọn ọmọkunrin wọnyi ki o ri oju rere lọdọ rẹ; nitoripe awa sa wá li ọjọ rere: emi bẹ ọ, ohunkohun ti ọwọ́ rẹ ba bá, fi fun awọn iranṣẹ rẹ, ati fun Dafidi ọmọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bi àwọn ọmọkùnrin rẹ léèrè, wọn ó sì sọ fún ọ. Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí rí ojú rere lọ́dọ̀ rẹ; nítorí pé àwa sá wá ní ọjọ́ àṣè: èmi bẹ̀ ọ́ ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá bà, fi fún àwọn ìránṣe rẹ, àti fún Dáfídì ọmọ rẹ.’ ”