1 Samuel 26:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọkunrin kan, ará Sifi lọ sọ fún Saulu ní Gibea pé, “Dafidi farapamọ́ sí òkè Hakila tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jeṣimoni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN ara Sifi si tọ̀ Saulu wá si Gibea, nwọn wipe, Ṣe Dafidi fi ara rẹ̀ pamọ nibi oke Hakila, eyi ti o wà niwaju Jeṣimoni?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ará Sífì tọ Ṣọ́ọ̀lù wá sí Gíbéà, wọn wí pé, “Dáfídì kò ha fi ara rẹ̀ pamọ́ níbi òkè Hákílà, èyí tí ó wà níwájú Jésímónì?”