1 Samuel 26:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi bá mú ọ̀kọ̀ ati ìgò omi Saulu ní ìgbèrí rẹ̀, òun pẹlu Abiṣai sì jáde lọ. Kò sí ẹnikẹ́ni ninu Saulu ati àwọn eniyan rẹ̀ tí ó mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, tabi tí ó jí nítorí OLUWA kùn wọ́n ní oorun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si mu ọ̀kọ na, ati igo omi na kuro nibi timtim Saulu: nwọn si ba ti wọn lọ, kò si si ẹnikan ti o ri i, tabi ti o mọ̀; kò si si ẹnikan ti o ji; gbogbo wọn si sùn; nitoripe orun àjika lati ọdọ Oluwa wá ti ṣubu lù wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì mú ọ̀kọ̀ náà àti ìgò omi náà kúrò níbi tìmùtìmù Ṣọ́ọ̀lù: wọ́n sì bá tiwọn lọ, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí i, tàbí tí ó mọ̀: kò sì sí ẹnikàn tí ó jí; gbogbo wọn sì sùn; nítorí pé oorun ìjìká láti ọdọ OLÚWA wá ti ṣubú lù wọ́n.