1 Samuel 26:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kọ́ ni alágbára jùlọ ní Israẹli? Kí ló dé tí o kò dáàbò bo ọba, oluwa rẹ? Láìpẹ́ yìí ni ẹnìkan wọ inú àgọ́ yín láti pa oluwa rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun Abneri pe, Alagbara ọkunrin ki iwọ nṣe ndan? tali o si dabi iwọ ni Israeli? njẹ ẽṣe ti iwọ ko tọju ọba oluwa rẹ? nitori ẹnikan ninu awọn enia na ti wọle wá lati pa ọba oluwa rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún Ábínérì pé, “Alágbára ọkùnrin kọ́ ni ìwọ bí? Ta ni ó sì dàbí ìwọ ni Ísírẹ́lì? Ǹjẹ́ èéṣe tí ìwọ kò tọ́jú ọba Olúwa rẹ? Nítorí ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn náà ti wọlé wá láti pa ọba OLÚWA rẹ.