1 Samuel 26:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ohun tí o ṣe yìí kò dára, mo fi OLUWA ṣe ẹ̀rí pé, ó yẹ kí o kú, nítorí pé o kò dáàbò bo oluwa rẹ, ẹni àmì òróró OLUWA. Níbo ni ọ̀kọ̀ ọba wà? Ibo sì ni ìgò omi tí ó wà ní ìgbèrí rẹ̀ wà pẹlu?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nkan ti iwọ ṣe yi kò dara. Bi Oluwa ti mbẹ, o tọ ki ẹnyin ki o kú, nitoripe ẹnyin ko pa oluwa nyin mọ, ẹni-àmi-ororo Oluwa. Njẹ si wo ibiti ọ̀kọ ọba gbe wà, ati igò omi ti o ti wà nibi timtim rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nǹkan tí ìwọ ṣe yìí kò dára. Bí OLÚWA ti ń bẹ, o tọ́ kí ẹ̀yin ó kú, nítorí pé ẹ̀yin kò pa olúwa yín mọ́, ẹni àmì òróró OLÚWA. Ǹjẹ́ sì wo ibi tí ọ̀kọ̀ ọba gbé wà, àti ìgò omi tí ó ti wà ní bi tìmùtìmù rẹ̀.”