1 Samuel 26:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Oluwa mi, gbọ́ ohun tí èmi iranṣẹ rẹ fẹ́ sọ. Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó gbé ọ dìde sí mi, kí ó gba ẹbọ ẹ̀bẹ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé eniyan ni, kí ègún OLUWA wá sórí olúwarẹ̀, nítorí wọ́n lé mi jáde, kí n má baà ní ìpín ninu ilẹ̀ ìní tí OLUWA fún àwọn eniyan rẹ̀. Wọ́n ń sọ fún mi pé kí n lọ máa bọ oriṣa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ emi bẹ ọ ọba, oluwa mi, gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹ rẹ. Bi Oluwa ba ti ru iwọ soke si mi, jẹ ki on ki o gbà ẹbọ; ṣugbọn bi o ba si ṣepe ọmọ enia ni, ifibu ni ki nwọn ki o jasi niwaju Oluwa; nitori nwọn le mi jade loni ki emi má gbe inu ilẹ ini Oluwa, wipe, Lọ, sin awọn ọlọrun miran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ èmi bẹ̀ ọ́, ọba, OLÚWA mi, gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ. Bí ó bá ṣe OLÚWA bá ti rú ọ sókè sí mi, jẹ́ kí òun o gba ẹbọ; ṣùgbọ́n bí o bá sì ṣe pé ọmọ ènìyàn ni, ìfibú ni kí wọn ó jásí níwájú OLÚWA; nítorí tí wọn lé mi jáde lónìí kí èmi má baà ní ìpín nínú ilẹ̀ ìní OLÚWA, wí pé, ‘Lọ sin àwọn ọlọ́run mìíràn.’