1 Samuel 26:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu dáhùn pé, “Mo ti ṣe ibi, máa bọ̀ Dafidi, ọmọ mi. N kò ní ṣe ọ́ ní ibi mọ́, nítorí pé ẹ̀mí mi níye lórí lójú rẹ lónìí. Mo ti hùwà òmùgọ̀, ohun tí mo ṣe burú pupọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wipe, Emi ti dẹṣẹ: yipada, Dafidi ọmọ mi: nitoripe emi kì yio wá ibi rẹ mọ, nitoriti ẹmi mi sa ti ṣe iyebiye li oju rẹ loni: wõ, emi ti nhuwa wère mo si ti ṣina jọjọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Èmi ti dẹ́sẹ̀: yípadà, Dáfídì ọmọ mi: nítorí pé èmi kì yóò wa ibi rẹ mọ́, nítorí tí ẹ̀mí mi sì ti ṣe ìyebíye lójú rẹ lónìí: wò ó, èmi ti ń hùwà òmùgọ̀, mo sì ti ṣìnà jọjọ.”