1 Samuel 26:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu dáhùn pé, “Ọlọ́run yóo bukun ọ, ọmọ mi, o óo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.” Dafidi bá bá tirẹ̀ lọ, Saulu sì pada sí ilé rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun Dafidi pe, Alabukunfun ni iwọ, Dafidi ọmọ mi: nitõtọ iwọ o si ṣe nkan nla, nitotọ iwọ o si bori. Dafidi si ba ọ̀na rẹ̀ lọ, Saulu si yipada si ibugbe rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì wí fún Dáfídì pé, “Alábùkún fún ni ìwọ, Dáfídì ọmọ mi: nítòótọ́ ìwọ yóò sì ṣe nǹkan ńlá, nítòótọ́ ìwọ yóò sì borí.” Dáfídì sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, Ṣọ́ọ̀lù sì yípadà sí ibùgbé rẹ̀.