1 Samuel 26:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki, ará Hiti ati Abiṣai ọmọ Seruaya, arakunrin Joabu pé, “Ta ni yóo bá mi lọ sí ibùdó Saulu?” Abiṣai dáhùn pé, “N óo bá ọ lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si dahun, o si wi fun Ahimeleki ọkan ninu awọn ọmọ Heti, ati fun Abiṣai ọmọ Seruia arákùnrin Joabu, pe, Tani o ba mi sọkalẹ lọ sọdọ Saulu ni ibudo? Abiṣai si wipe, emi o ba ọ sọkalẹ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì dáhùn, ó sì wí fún Áhímélékì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Hétì, àti fún Ábíṣáì ọmọ Sérúíà ẹ̀gbọ́n Jóábù, pé, “Ta ni yóò ba mi sọ̀kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Ṣọ́ọ̀lù ni ibùdó?” Ábíṣáì sì wí pé, “Èmi yóò ba ọ sọ̀kalẹ̀ lọ.”