1 Samuel 26:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi ati Abiṣai bá lọ sí ibùdó Saulu ní òru ọjọ́ náà, Saulu sì ń sùn ní ààrin àgọ́, ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ lẹ́bàá ìrọ̀rí rẹ̀. Abineri ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì sùn yí i ká.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Dafidi ati Abiṣai si tọ awọn enia na wá li oru: si wõ, Saulu dubulẹ o si nsun larin kẹkẹ, a si fi ọ̀kọ rẹ̀ gunlẹ ni ibi timtim rẹ̀: Abneri ati awọn enia na si dubulẹ yi i ka.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti Ábíṣáì sì tọ àwọn ènìyàn náà wá lóru: sì wò ó, Ṣọ́ọ̀lù dùbúlẹ̀ ó sì ń sùn láàrin kẹ̀kẹ́, a sì fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ ni ibi tìmùtìmù rẹ̀: Ábínérì àti àwọn ènìyàn náà sì dùbúlẹ̀ yí i ká.