1 Samuel 27:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi rò ní ọkàn rẹ̀ pé Saulu yóo pa òun ní ọjọ́ kan, nítorí náà ohun tí ó dára jù ni kí òun sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ó ní Saulu yóo dẹ́kun láti máa wá òun kiri ní ilẹ̀ Israẹli, òun óo sì fi bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
DAFIDI si wi li ọkàn ara rẹ̀ pe, njẹ ni ijọ kan l'emi o ti ọwọ́ Saulu ṣegbe, ko si si ohun ti o yẹ mi jù ki emi ki o yara sa asala lọ si ilẹ awọn Filistini: yio su Saulu lati ma tun wá mi kiri ni gbogbo agbegbe Israeli: emi a si bọ li ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí ní ọkàn ara rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ni ìjọ kan ni èmi yóò ti ọwọ́ Ṣọ́ọ̀lù ṣègbé, kò sì sí ohun tí ó yẹ mí jù kí èmi yára sá àsálà lọ sórí ilẹ̀ àwọn Fílístínì: yóò sú Ṣọ́ọ̀lù láti máa tún wa mi kiri ní gbogbo agbégbé Ísírẹ́lì: èmi a sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.”