1 Samuel 27:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi kò dá ẹnìkankan sí yálà ọkunrin tabi obinrin kí wọ́n má baà mú ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lọ sí Gati, bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ń ṣe ní gbogbo ìgbà tí ó ń gbé ààrin àwọn ará Filistia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi kò si da ọkunrin tabi obinrin si lãye, lati mu ihin wá si Gati, wipe, Ki nwọn ki o má ba sọ ọ̀rọ wa nibẹ, pe, Bayi ni Dafidi ṣe, ati bẹ̃ni iṣe rẹ̀ yio si ri ni gbogbo ọjọ ti yio fi joko ni ilu awọn Filistini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì kò sì dá ọkùnrin tàbí obìnrin sí láàyè, láti mú ìròyìn wá sí Gátì, wí pé, “Ki wọn máa bá à sọ ọ̀rọ̀ wa nibẹ̀, pé, ‘Báyìí ni Dáfídì ṣe’ ” Àti bẹ́ẹ̀ ni iṣe rẹ̀ yóò sì rí ni gbogbo ọjọ́ ti yóò fí jókòó ni ìlú àwọn Fílístínì.