1 Samuel 27:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Akiṣi gba Dafidi gbọ́, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀, kórìíra rẹ̀ lọpọlọpọ, nítorí náà yóo jẹ́ iranṣẹ mi laelae.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Akiṣi si gba ti Dafidi gbọ́, wipe, On ti mu ki Israeli ati awọn enia rẹ̀ korira rẹ̀ patapata, yio si jẹ iranṣẹ mi titi lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ákíṣì sì gba ti Dáfídì gbọ́, wí pé, “Òun ti mú kí Ísírẹ́lì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ kóríra rẹ̀ pátapáta, yóò si jẹ́ ìránṣẹ́ mi títí láé.”