1 Samuel 27:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi sì sọ fún Akiṣi pé, “Bí mo bá rí ojurere rẹ, jọ̀wọ́ fún mi ní ààyè ní ọ̀kan ninu àwọn ìletò agbègbè yìí kí n máa gbé. Kí ló dé tí èmi iranṣẹ rẹ yóo máa gbé inú ìlú kan náà pẹlu rẹ?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Bi o ba jẹ pe emi ri ore ọfẹ loju rẹ, jẹ ki wọn ki o fun mi ni ibi kan ninu awọn ileto wọnni; emi o ma gbe ibẹ: ẽṣe ti iranṣẹ rẹ yio si ma ba ọ gbe ni ilu ọba?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì wí fún Ákíṣì pé, “Bí ó bá jẹ́ pé èmi rí oore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ̀, jẹ́ kí wọn ó fún mi ní ibìkan nínú àwọn ìletò wọ̀nyí; èmi yóò máa gbé ibẹ̀: èéṣé tí ìránṣẹ́ rẹ yóò sì máa bá ọ gbé ní ìlú ọba.”