1 Samuel 27:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkókò náà, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti àwọn ará Geṣuri, ati àwọn ará Girisi ati àwọn Amaleki, tí wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, títí dé Ṣuri ati ilẹ̀ Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ, nwọn si gbe ogun ti awọn ara Geṣuri, ati awọn ara Gesra, ati awọn ara Amaleki: awọn wọnyi li o si ti ngbe ni ilẹ, na nigba atijọ, bi iwọ ti nlọ si Ṣuri titi o fi de ilẹ Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ, wọ́n sì gbé ogun ti àwọn ará Gésúrì, àti àwọn ara Gésírà, àti àwọn ará Ámálékì àwọn wọ̀nyí ni ó sì tí ń gbé ní ilẹ̀ náà, láti ìgbà àtijọ́, bí ó ti fẹ̀ lọ sí Ṣúrì títí ó fí dé ilẹ̀ Éjíbítì.