1 Samuel 28:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó ṣe, àwọn ará Filistia kó ara wọn jọ láti bá Israẹli jagun. Akiṣi sọ fún Dafidi pé, “Ìwọ ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ yóo jà fún mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, ni ijọ wọnni, awọn Filistini si ko awọn ogun wọn jọ, lati ba Israeli jà. Akiṣi si wi fun Dafidi pe, Mọ̀ dajudaju pe, iwọ o ba mi jade lọ si ibi ija, iwọ ati awọn ọmọkunrin rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, àwọn Fílístínì sì kó àwọn ogun wọn jọ, láti bá Ísírẹ́lì jà. Ákíṣì sì wí fún Dáfídì pé, “Mọ dájúdájú pé, ìwọ yóò bá mi jáde lọ sí ibi ìjà, ìwọ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ.”