1 Samuel 28:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA yóo fa ìwọ ati Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Ní ọ̀la ni ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ yóo kú; OLUWA yóo sì fa àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa yio si fi Israeli pẹlu iwọ le awọn Filistini lọwọ: li ọla ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio pẹlu mi: Oluwa yio si fi ogun Israeli le awọn Filistini lọwọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA yóò sì fi Ísírẹ́lì pẹ̀lú ìwọ lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́: ní ọ̀la ni ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò pẹ̀lú mi: OLÚWA yóò sì fi ogun Ísírẹ́lì lé àwọn Fílístínì lọ́wọ́.”